
Ki lo njo o lowo,
Ti oo le fi jole,
Too fi n tapa kaka s'awon to junilo,
Kinni majesin ni,
To n gun gara-gara,
To fi n sope kosiru oun.
Ipo wo lowa loni teni kan o ti gun sokale, mo beere wo.
Nje Iwo ti ri ola aye kan ti o lopin?
Boya lofi ranti pe obe eyin igbako, wape nii tan.
Nje ni o mo itan eye a tan ni gban-an-ni?
Gbogbo ibeere ohun asamo akewi lati fa o leti ni.
Bola ba de fun o, ran ti ola.
Boowa nipo atata, mase yo finkin, bi afegbo-lu-odo.
Mase biiwofa toyotan,
To lolowo oun ko je nkan.
Ekulu to so pako Luke lojosi,
Ranti pe ota ati ahaya lo tori e bo ata.
Ki waa ni faari olaaye to gbe loju,
Kinni karahan-un akaba too gun to o sokale lojokan.
Bowo re ba te ipo kan ore,
Mase sopako seyin, koo ni kosi iru re.
Nitori, beegun bamo pe oun yoo pada deeyan,
Iwonba ni yoo roro mo ninu eku.
Oluko loje, mase yan akekoo je, ibi agba bawa lomode e ba.
Oga ile ise niwo Awe,
Se pele pelu osise abe re,
Bi kinniun se joba eranko to, ko le ko iyan awon eranko keekeeke kan kere.
Awon agba omoran loro oun leye.
Se gaaru mo niwon,
Din laale re ku,
Baye badun fun o lonii,
Akewi ni o ma sope kosiru re.
Mo fewi fa o leti ore,
Koo ma baa jin sofin,
Alabahun to n se jeje, iku n paa,
Bele ntase opolo to n jan ara re mole kiku o toode.
Iwa Pele dowo re o,
Ki o le baa sole pe.
Add new comment