TÚJÚKÁ: Adùn níí gbẹyìn ewúro

Author: 
Ọ̀gbẹ́ni Wasiu Ibrahim
Category: 

TÚJÚKÁ: Adùn níí gbẹyìn ewúro

Kín ló ń kún ọ nínú tóo fi rojú koko,
Ọ̀̀rọ̀ wo ló ń dùn ọ́ l'ọ́kàn tó fàròkàn,
Kín ni ìbáa fa sábàbí ìkáwọ́ bọtan,
Tó fi wá á jẹ́ pé ikú l'ókù tó n retí,
Tóo fí ń wojú ọ̀run bíi kókè
Ó ya bọ́ọ́lẹ̀

Ọ̀rẹ́, ò bá farabalẹ̀ térò pa o jàre,
Ìwo yìí gan l'Akéwì ń bááwí
Ìrònú ò da ǹkan, ká káwó bọtan ò tán ìṣòro,

S'ówó ló tá ẹ lọ́wọ́,
Àbí gbèsè gegere ló fẹ́sọ ẹ́ dẹlẹ́jẹ̀ ríru,
B'ẹ́mì báwà, ìrètí sí nbẹ
Ọ̀sán lọ́ ń pọ́n ìtálẹ̀ lójú,
B'ọ́bá dalẹ́, á di olọ́únjẹ

Add new comment