
TÚJÚKÁ: Adùn níí gbẹyìn ewúro
Kín ló ń kún ọ nínú tóo fi rojú koko,
Ọ̀̀rọ̀ wo ló ń dùn ọ́ l'ọ́kàn tó fàròkàn,
Kín ni ìbáa fa sábàbí ìkáwọ́ bọtan,
Tó fi wá á jẹ́ pé ikú l'ókù tó n retí,
Tóo fí ń wojú ọ̀run bíi kókè
Ó ya bọ́ọ́lẹ̀
Ọ̀rẹ́, ò bá farabalẹ̀ térò pa o jàre,
Ìwo yìí gan l'Akéwì ń bááwí
Ìrònú ò da ǹkan, ká káwó bọtan ò tán ìṣòro,
S'ówó ló tá ẹ lọ́wọ́,
Àbí gbèsè gegere ló fẹ́sọ ẹ́ dẹlẹ́jẹ̀ ríru,
B'ẹ́mì báwà, ìrètí sí nbẹ
Ọ̀sán lọ́ ń pọ́n ìtálẹ̀ lójú,
B'ọ́bá dalẹ́, á di olọ́únjẹ
Ṣé ìjákulẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ni,
Tóo fi wá ròpé ikú nìkan lọ̀nà àbáyọ,
Ah! Ọ̀rẹ́ẹ̀ mi akẹ̀kọ̀ọ́
Ẹni tí ó kú, lóni igbó òkè àti tìsàlẹ̀.
Ṣe ara ní gírí, kóo tún ìwé rẹ gbọ̀n,
Olú le bá o sẹ́, kóo tún fakoyo.
F'ọkàn sọ́rọ̀ ẹnu akéwì,
Máṣe torí pé ẹgbẹ́ rẹ ní oun tóò ní,
Kóowá nílé ayé ti sú ọ,
Ilẹ̀ tí a o tíì kọ́,
Ó ṣàgbà èyí táa ti kólé sí.
Oni lee koro jojo,
Ipò yòówù tí ẹ̀dá lewà
Adùn níí gbẹ̀yìn ewúro.
bá ò kú, ìṣe ò tán.
Máṣe fìròonú ṣọra rẹ dìdàkudà
(A fi sori gbogbo eniyan to ni depression)
Add new comment